News and conversations in colloquial Yoruba

EPISODE 12: QUEEN ELIZABETH CELEBRATES PLATINUM JUBILEE


Listen Later

This news episode describes the platinum jubilee of Queen Elizabeth II. You would learn vocabulary on monarchy, cultural and language points in Yoruba, as well as how to describe an event. 

 Increase your confidence in Yoruba through facilitated dialogue with other learners by joining the Yoruba conversation practice community. To register, send a WhatsApp message to 2348165547356 or an email to [email protected].

Here is the news transcript: 

Ọbabìnrin ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ṣe ayẹyẹ àádọ́rin ọdún tí ó gun orí oyè láìpẹ́ yìí. Ọjọ́ mẹ́rin ni wọ́n fi ṣe ayẹyẹ náà. ̣Ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́bọ̀, ó dẹ̀ parí ní ọjọ́ ìsinmi. Ètò náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ayẹyẹ tí àwọn èyàn wọ oríṣiríṣi àwọ̀ káàkiri ìgboro. Àwọn Ológun náà gun ẹṣin púpọ̀ fún ayẹyẹ náà ní ọjọ́ ẹtì. Ní alẹ́ ọjọ́bọ̀, wọ́n tan iná tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ káàkiri ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì. Alẹ́ ọjọ́ náà ni ìkéde wá láti ààfin pé ọbabìnrin náà ò ní lè kópa nínú ayẹyẹ ìjọsìn nítorí àìlera ẹ̀.  Yàtọ̀ sí ayẹyẹ ìsìn ìdúpẹ́ náà, Ọbabìnrin Elizabeth kejì ò yọjú sí àwọn ayẹyẹ míràn. Ní ọjọ́ àbámẹ́ta, wọ́n ṣe ayẹyẹ fífi ẹṣin sáré. Wọ́n ṣe àṣekágbá ayẹyẹ náà ní ọjọ́ ìsinmi. Àwọn eléré oríṣiríṣi dá àwọn èyà́n lárayá. Jíjẹ mímu náà pọ̀ nínú ayeye náà. Sáájú, Ọbabìnrin Elizabeth kejì ti kéde pé kí Camilla di ayaba tí ọkọ ẹ̀ Charles bá gun orí oyè.


...more
View all episodesView all episodes
Download on the App Store

News and conversations in colloquial YorubaBy Mojisola Alawode