News and conversations in colloquial Yoruba

Episode 6: Football News; Nigeria-Sudan Match


Listen Later

This episode is about football vocabulary. You would learn how to describe a match. Here is the news transcript: Nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Nigeria àti Sudan, ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù super Eagles na Sudan. Wọn ò tíì lò tó ìṣẹ́jú mẹ́wàa ́lóri pápá tí Nigeria fi kọ́kọ́ jẹ àmì ayò kan. Kía tó ṣẹ́jú pẹ́, Nigeria tún ti gbá góòlù kan síi. Ó jẹ́ àmì ayò méjì sí òdo ní abala àkọ́kọ́. Láàrín ìṣẹ́jú kan tí abala kejì ìdíje bẹ̀rẹ̀, ọmọ Nigeria ìmíì tún ju góòlù kan sí àwọ̀n Sudan. Ó di àmì ayò mẹ́ta sí òdo. Pènárítì ni Sudan fi jẹ àmì ayò kan ṣo tí wọ́n ní tí ó fi jẹ́ àmì ayò mẹ́ta sí eyọ kan ní ìparí ìfẹsẹ̀wọnsè náà. Sudan ti kọ́kọ́ gba ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ilè Africa ní ọdún 1970, nígbà tí wọ́n gba àlejò ìdíje AFCON ṣùgbọ́n Nigeria gba ife ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ ní ọdún 1980.

...more
View all episodesView all episodes
Download on the App Store

News and conversations in colloquial YorubaBy Mojisola Alawode