News and conversations in colloquial Yoruba

Episode 7: Heavy snow storm in America- Nor'easter


Listen Later

This news episode is on Nor'easter, the heavy snowstorm that hit the Eastern states of the United States of America, recently. You would learn vocabulary on whether using some expressions commonly used by native speakers. Here is the news transcript:

 Láìpẹ́ yìí, ǹkan ò rọgbọ ní àwọn agbègbè kàn kan ní ilà oòrùn America. Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún mẹ́rin, wọ́n ní ìji yìnyín líle tí ó jẹ́ kí àwọn ǹkan dẹnukọlẹ̀. Orúkọ ìji yìnyín líle náà ni Nor’easter. Àwọn ìpínlẹ̀ márùn-ún tí ó bà ti kéde “ǹkan ò fararọ” pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé kí àwọn olùgbé ibẹ̀ má jáde sí ojú pópó rárá fún àbò ara wọn.

Àwọn awòye ojú ọjọ́ kìlò pé ó ṣeéṣe kí omíyalé ṣẹlẹ̀ ní àwọn agbègbè tí ó súnmó etí omi. Wọ́n tún sọ pé lásìkò ìji yìyín líle yìí, afẹ́fẹ́ tútù máa dàpọ̀ mọ́ oru tí ó ń jáde nínú òkun. Eléyìí máa fa àyípadà ojú ọjọ́ ránpẹ́.

Yàtọ̀ sí èyí, wọ́́n ní ó ṣeéṣe kí ìji yìnyín líle náà bo agbègbè Boston mọ́lè pátápátá pẹ̀lú yìnyín tí ó ga tó ìwọn ẹsẹ̀ bàtà méjì. Nítorí náà , àjọ tí ó ń mọ́jútó àyípadà ojú ọjọ́ ní Boston sọ pé ìrìnàjò pàjáwìrì nìkan ni kí àwọn aláṣẹ fi àyè gbà lásìkò yí. Ìrìn àjò bàálúù tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún ni wọ́n fagilé láàrín ọjọ́ Friday sí ọjọ́ Sunday. Àárọ̀ kùtù ọjọ́ Saturday ni ọwọ́ ìji yìnyín líle náà bẹ̀rẹ̀ siní kan àwọn etí omi nílẹ̀ America tí yìnyín dẹ̀ ń jábọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀.

...more
View all episodesView all episodes
Download on the App Store

News and conversations in colloquial YorubaBy Mojisola Alawode