Yoruba Educational Series

LETA AIGBEFE


Listen Later

Koko Ise: Leta Aigbefe

Leta Aigbefe ni leta ti a maa n ko,  nigba ti a ba n wa ise tabi ti a ba ni nnkan gba lowo awon oga olu ile-ise kan tabi omiran.


 Aye ko si fun wa lati da apara tabi se efe kankan nigba ti a ba n ko irufe leta yii. 


Awon ti a maa n ko leta wonyi si ni:

1. Ile-ise ijoba bi apeere: Ile-ise eto eko. 

2. Ile-ise amohun-maworan. 

3. Ile-ise itewe. 

4. Yunifasiti tabi ile-iwe giga miiran. 

5. Ajo W.A.E.C, N.E.P.A, Water corporation ati bee bee lo. 


Ki a to le se aseyori ninu kiko leta aigbefe,  a ni lati tele awon igbese wonyi.


Igbese Inu Leta Aigbefe

1. Adiresi eni ti o n ko leta: Apa otun, ni oke ni adiresi eni ti o n ko leta maa n wa. 


2. Deeti: Ojo ti a ba ko leta se pataki fun iranti lojo iwaju. Isale adiresi ni eyi nilati wa, a si gbodo ko o ni kikun. Bi apeere:

10th May, 2020;

29th June, 2020;

tabi: 10-05-2020;

29-06-2020.


3. Ipo ati adiresi eni ti a ko leta si: Owo osi oke leta ni a o ko ipo ati adiresi eni ti a n ko leta naa si, ila to tele ila ti a ko deeti si ni eyi yoo wa. 


4. Ibere leta: Bere leta re ni owo osi pelu: Alaga,  Alagba, Olootu, Oga mi Owon, Kabiyesi ati bee bee lo. 


AKIYESI

Ko si ikini leyin oro-ibere leta aigbagbefe. A ko gbodo wi pe "Se alaafia ni o wa". 


5. Ori oro tabi Akole leta: A ni lati fun leta aigbefe ni ori-oro ti o ba koko ero inu leta naa mu regiregi. 


6. Inu leta: Ori ohun ti a fe so gan-an ni a gbodo lo taara. A ko gbodo da apara kan-kan bee ni a ko gbodo se awawi asan bi a se so saaju. 


7. Ipari leta: "Emi ni tiyin" ni a gbodo fi pari leta aigbefe. 


8. Oruko eni ti o ko leta: Isale gbolohun idagbere ti a fi pari leta wa ni oruko eni ti o ko leta gbodo wa. A ni lati ko oruko wa ati ti baba wa. Dandan ni ki a fihan boya okunrin ni wa tabi obinrin. 

Bi apeere: Femi Adelaja (Mr), Joke Raheem (Miss).

...more
View all episodesView all episodes
Download on the App Store

Yoruba Educational SeriesBy Cecilia

  • 5
  • 5
  • 5
  • 5
  • 5

5

4 ratings