Leta Aigbefe ni leta ti a maa n ko, nigba ti a ba n wa ise tabi ti a ba ni nnkan gba lowo awon oga olu ile-ise kan tabi omiran.
Aye ko si fun wa lati da apara tabi se efe kankan nigba ti a ba n ko irufe leta yii.
Awon ti a maa n ko leta wonyi si ni:
1. Ile-ise ijoba bi apeere: Ile-ise eto eko.
2. Ile-ise amohun-maworan.
4. Yunifasiti tabi ile-iwe giga miiran.
5. Ajo W.A.E.C, N.E.P.A, Water corporation ati bee bee lo.
Ki a to le se aseyori ninu kiko leta aigbefe, a ni lati tele awon igbese wonyi.
1. Adiresi eni ti o n ko leta: Apa otun, ni oke ni adiresi eni ti o n ko leta maa n wa.
2. Deeti: Ojo ti a ba ko leta se pataki fun iranti lojo iwaju. Isale adiresi ni eyi nilati wa, a si gbodo ko o ni kikun. Bi apeere:
3. Ipo ati adiresi eni ti a ko leta si: Owo osi oke leta ni a o ko ipo ati adiresi eni ti a n ko leta naa si, ila to tele ila ti a ko deeti si ni eyi yoo wa.
4. Ibere leta: Bere leta re ni owo osi pelu: Alaga, Alagba, Olootu, Oga mi Owon, Kabiyesi ati bee bee lo.
Ko si ikini leyin oro-ibere leta aigbagbefe. A ko gbodo wi pe "Se alaafia ni o wa".
5. Ori oro tabi Akole leta: A ni lati fun leta aigbefe ni ori-oro ti o ba koko ero inu leta naa mu regiregi.
6. Inu leta: Ori ohun ti a fe so gan-an ni a gbodo lo taara. A ko gbodo da apara kan-kan bee ni a ko gbodo se awawi asan bi a se so saaju.
7. Ipari leta: "Emi ni tiyin" ni a gbodo fi pari leta aigbefe.
8. Oruko eni ti o ko leta: Isale gbolohun idagbere ti a fi pari leta wa ni oruko eni ti o ko leta gbodo wa. A ni lati ko oruko wa ati ti baba wa. Dandan ni ki a fihan boya okunrin ni wa tabi obinrin.
Bi apeere: Femi Adelaja (Mr), Joke Raheem (Miss).